Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina

Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura pẹlu Ọlọhun pe ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa oun ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara tabi ẹni ti o yatọ si awọn mejeeji, ti ipepe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- de etiigbọ rẹ, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ ninu rẹ afi ki o wa ninu awọn ara ina ti o maa ṣe gbere nibẹ lailai.

فوائد الحديث

Kikari ìránṣẹ́ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si gbogbo aye, ati pe itẹle rẹ jẹ dandan, ati pipa gbogbo àwọn ofin rẹ pẹlu Sharia rẹ.

Ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ si Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ini adisọkan igbagbọ rẹ pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i ninu awọn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun maa ba wọn patapata- ko nii ṣe e ni anfaani.

Ẹni ti ko ba gbọ nipa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti ipepe Isilaamu ko si de etiigbọ rẹ, oun jẹ ẹni ti o ni àwíjàre, alamọri rẹ ni ọrun si wa lọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

Ṣíṣe anfaani pẹlu Isilaamu maa wa si ìmúṣẹ koda ki o jẹ pe o ku diẹ ti eeyan maa ku, koda ki o jẹ ninu aarẹ ti o le koko, niwọn igba ti ẹmi ko ba i tii de ọna ọfun.

Titun ẹsin awọn alaigbagbọ ṣe- ti Juu ati Nasara n bẹ ninu wọn- jẹ aigbagbọ.

Didarukọ Juu ati Nasara- ninu hadiisi náà- jẹ itaniji fun ẹni ti o yàtọ̀ si wọn; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe iwe n bẹ fun Juu ati Nasara, ti ọrọ wọn ba wa ri báyìí, a jẹ pe ẹni tí o yàtọ̀ si wọn ti iwe ko si fun wọn ni ẹtọ si i ju wọn lọ, ati pe gbogbo wọn, wiwọ inu ẹsin rẹ jẹ dandan fun wọn ati itẹle rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

التصنيفات

Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-