Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni

Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni

Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni, Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun wọn ni ọjọ igbedide ti wọn ba ti san awọn eniyan lẹsan pẹlu awọn iṣẹ wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ti ẹ maa n ṣe karimi fun ni aye, ki ẹ si wo boya ẹ maa ri ẹsan kankan lọdọ wọn?"

[O ni alaafia] [Ahmad ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju nnkan ti o pọ julọ ti oun n bẹru rẹ lori awọn ijọ rẹ ni: Ẹbọ kékeré, oun ni: Ṣekarimi; ki o maa ṣiṣẹ nitori awọn eniyan. Lẹyin naa o sọ nipa iya awọn oniṣekarimi ni ọjọ igbedide, pe wọn maa sọ fun wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ẹni ti ẹ n ṣiṣẹ nitori wọn, ki ẹ si wo boya wọn kapa sisan yin lẹ́san ati fifun yin ni ẹsan lori iṣẹ yẹn?!

فوائد الحديث

Jijẹ dandan mimọ iṣẹ kanga fun Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ati ikilọ kuro nibi ṣekarimi.

Ile koko ini aanu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori ìjọ rẹ ati iko akolekan rẹ lori imọna wọn ati ṣiṣe iṣiti rẹ fun wọn.

Ti o ba ṣe pe ibẹru rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nìyí, ti o si n ba awọn saabe sọ̀rọ̀, ti wọn si ṣe pe awọn ni aṣaaju awọn ẹni rere, a jẹ pe ibẹru rẹ lori awọn ti wọn wa lẹyin wọn lo le julọ.

التصنيفات

Ida ọrọgun pọ mọ Ọlọhun, Ida ọrọgun pọ mọ Ọlọhun, Ikẹ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, Ikẹ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-