إعدادات العرض
Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin
Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin
Lati ọdọ ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni àárọ̀ jiju okuta ipari, ti o si wa lori rakunmi rẹ pé: "Ba mi mu okuta kekere kan" mo wa mu awọn okuta kekere meje fun un, awọn ni okuta kéékèèké tí a maa n fi ìka méjì jù, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii ju wọn si atẹlẹwọ rẹ, o si n sọ pe: "Awọn iru awọn wọnyi ni ẹ maa ju" lẹyin naa o sọ pe: "Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Kurdî Kiswahili Português සිංහල Svenska ગુજરાતી አማርኛ ئۇيغۇرچە Tiếng Việt Hausa پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or नेपाली Malagasy മലയാളം Čeština Oromoo Română Kinyarwanda Nederlands Soomaali తెలుగు ไทย Lietuvių Српски Українська Shqip ಕನ್ನಡ Wolof Moore ქართული Magyarالشرح
Ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n sọ pe oun wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ iduran ni àárọ̀ jiju okuta jamratul ákọ́bà ni hajj idagbere, Bayii ni o ba pa a láṣẹ ki o ba a sa okuta ti o maa jù, o si ba a sa òkúta meje, ikan nibẹ da gẹgẹ bii èso himmas tabi èso bunduk, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe wọn si ọwọ rẹ lẹyin naa o mì wọn, o wa sọ pe: Irú wọn ní ìwọ̀n ni ki ẹ jù, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ nipa aṣẹju ati imu nnkan le koko ati kikọja aala nibi awọn alamọri ẹsin, ati pe kikọja aala ko iparun ba awọn ijọ ìṣáájú ati aṣeju ati imu nnkan le koko nibi ẹsin.فوائد الحديث
Kiko kuro nibi aṣẹju nibi ẹsin, ati alaye aida igbẹyin rẹ, ati pe o jẹ okunfa fun iparun.
Ìwòye sí àwọn ti wọn ṣáájú wa ninu awọn ijọ lati jina si nnkan ti wọn kósí ninu awọn aṣiṣe.
Isẹnilojukokoro lori kikọṣe sunnah.
التصنيفات
Awọn ibeere asiko aimọkan