Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀

Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé: Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pé dajudaju ẹniti ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ oun ni ọjọ Igbende ni ẹnikẹni tí ó bá sọ pé: "Ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah pẹlu ododo lati inu ọkan rẹ̀" iyẹn ni pe: ko si ẹnikẹni ti a gbọdọ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pe ó gbọdọ là kuro nibi ẹbọ ati kárími.

فوائد الحديث

Fífi ìṣìpẹ̀ rinlẹ̀ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni ọjọ ikẹyin, ati pé ìṣìpẹ̀ naa ko nii sí fun ẹnikankan ayafi awọn tí wọ́n ṣe Ọlọhun lọ́kan ṣoṣo.

Ìṣìpẹ̀ rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - oun ni ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ si Ọlọhun Ọba fun awọn tí ó yẹ kí wọ́n wọ ina Jahannama ninu awọn oluṣọlọhun lọ́kan pé kí wọ́n má wọ inu rẹ̀, ati pé kí awọn tí ó ti wà ninu ina lè jáde kuro ninu rẹ̀.

Ọlá tí n bẹ fun gbolohun iṣọlọhun lọ́kan tó jẹ́ ododo mímọ́ fun Ọlọhun Ọba, ati títóbi orípa gbolohun naa.

Gbolohun iṣọlọhun lọ́kan yoo maa di òtítọ́ pẹlu mímọ itumọ rẹ̀, ati fífi nǹkan ti o n bèèrè fun ṣiṣé ṣe.

Ọlá tí n bẹ fún Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ati ìtaraṣàṣà rẹ̀ sí ìmọ̀.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah