Ẹni ti o ba kirun tutu mejeeji o maa wọ alujanna

Ẹni ti o ba kirun tutu mejeeji o maa wọ alujanna

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba kirun tutu mejeeji o maa wọ alujanna"

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa lojukokoro lori akolekan irun tutu mejeeji, awọn mejeeji ni irun Asunbaa ati irun Alaasari, o si fun wa ni iro idunnu pe ẹni ti o ba mu mejeeji wa pẹlu ẹtọ mejeeji ninu asiko ati ni janmọọn ati eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, mejeeji maa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ.

فوائد الحديث

Ọla ti o n bẹ fun àbójútó irun alufajari ati alaasari; nitori pe alufajari maa n waye lasiko igbadun oorun, ti alaasari si maa n waye ni asiko iko-airoju ọmọniyan pẹlu iṣẹ rẹ, ẹni ti o ba n bójú tó mejeeji, o sunmọ ki o rọrun fun un lati bójú tó awọn irun yoku.

Wọn sọ irun alufajari ati alaasari ni tutu mejeeji; nitori pe irun alufajari otutu oru n bẹ nibẹ, ti otutu ọsan si n bẹ nibi irun alaasari, bi o ti lẹ jẹ pe asiko ti o maa n waye maa n gbóná, ṣùgbọ́n o maa n fuyẹ ju ìgbóná asiko ti o ṣíwájú rẹ lọ, tabi ki sisọ wọn bẹẹ jẹ lábẹ́ fifi ọ̀rọ̀ kan borí ọ̀kan ni, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ pe: Al-qomoraan fun oorun ati òṣùpá.

التصنيفات

Ọla ti o n bẹ fun irun