“Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”

“Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'hud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”

[O ni alaafia] [Ibnu Maajah ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé àwọn nǹkan ti ṣíṣe wọn wa ninu ẹbọ, ninu wọn ni: Akọkọ: Ọfọ̀: Oun ni ọ̀rọ̀ ti àwọn ara àsìkò ki Isilaamu to de fi maa n ṣe ìwòsàn, ti o ni ẹbọ nínú. Ìkejì: Àsokọ́ra lati ara ìlẹ̀kẹ̀ ati nǹkan ti o jọ ọ: Eyi ti wọn maa n so kọ ọmọdé lọrun, ati awọn ẹran-ọ̀sìn, ati nǹkan ti o yatọ si i, lati ti ojukoju dànù. Ikẹta: Oogun ifẹran: Eyi ti wọn ṣe lati jẹ ki ọkọ ati ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí wa nínú ẹbọ; torí pé o wa ninu fifi nǹkan ṣe okùnfà, ti kii sii ṣe okùnfà ti o ba òfin mu ti o rinlẹ pẹ̀lú ẹ̀rí, kii sii ṣe okùnfà ti ìmọ̀lára ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí. Ṣùgbọ́n àwọn òkùnfà ti o ba ofin mu gẹ́gẹ́ bii kika Kuraani, tabi eyi ti o jẹ ti ìmọ̀lára gẹ́gẹ́ bii àwọn oògùn ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí, èyí ni ẹtọ pẹlu adisọkan pe okùnfà ni, ati pe àǹfààní ati ìnira wa lọ́wọ́ Ọlọhun.

فوائد الحديث

Ṣiṣọ taohid ati adisọkan kúrò nibi nǹkan ti o maa ba a jẹ́.

Ṣíṣe lilo ọfọ ti ẹlẹbọ ati àsokọ́ra ati oogun ifẹran ni eewọ.

Adisọkan ọmọniyan nipa awọn mẹtẹẹta yii pe okùnfà ni wọn: Oun ni ẹbọ kekere; torí pé o ṣe ohun ti kii ṣe okùnfà ni okùnfà, ṣùgbọ́n ti o ba ni adisọkan pe oun ni yoo ṣe anfaani tabi fa inira funra rẹ, ìyẹn ni ẹbọ ńlá.

Ikilọ kuro nibi ṣíṣe àwọn òkùnfà ti ẹlẹbọ ati eyi ti o jẹ eewọ.

Ṣíṣe ọfọ ni eewọ, ati pe ẹbọ ni, ayafi eyi ti o ba ba sharia mu.

O tọ́ ki ọkàn rọ̀ mọ́ Ọlọhun nìkan, ọdọ Rẹ ni ìnira ati àǹfààní ti n wa, ko ni orogun, ko si ẹni ti o le mu oore wa ayafi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu lọ ayafi Ọlọhun.

Ọfọ ti o tọ́ ni eyi ti o ko májẹ̀mú mẹta sinu:

1- Ki a ni adisọkan pe okùnfà ni wọn, wọn ko lee ṣe anfaani ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun.

2- Ki wọn jẹ pẹlu Kuraani ati awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn adua ti Anọbi, ati awọn adua ti wọn ba sharia mu.

3- Ki wọn jẹ pẹlu èdè ti a gbọye, ti ko si nii ni ìwé oògùn ati ẹtan ninu.

التصنيفات

Iwosan ti shariiah, Iwosan ti shariiah