“Gbogbo dáadáa sàárà ni”

“Gbogbo dáadáa sàárà ni”

Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Gbogbo dáadáa sàárà ni”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo dáadáa ati àǹfààní fun ẹlòmíràn, bóyá ọrọ ni tabi iṣẹ, o maa jẹ sàárà, ẹ̀san si n bẹ nibẹ.

فوائد الحديث

Sàárà kò mọ lori nǹkan ti èèyàn n yọ jáde ninu dúkìá, bi ko ṣe pe o ko gbogbo oore ti ọmọniyan n ṣe tàbí sọ sínú, ti o si maa de ọdọ ẹlòmíràn.

O n bẹ nibẹ isẹnilojukokoro lati maa ṣe dáadáa ati gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun ẹlòmíràn.

Ki èèyàn ma fi ojú kere dáadáa kankan, kódà ki o kéré.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ rere