“Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n alágbára gangan ni ẹni tí ó bá le kápá ẹ̀mí rẹ nígbà ìbínú”

“Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n alágbára gangan ni ẹni tí ó bá le kápá ẹ̀mí rẹ nígbà ìbínú”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n alágbára gangan ni ẹni tí ó bá le kápá ẹ̀mí rẹ nígbà ìbínú”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe agbára gidi kii ṣe agbára ti ara, tabi ẹni ti o ba maa dá alágbára mìíràn mọ́lẹ̀. Alágbára gangan ni ẹni tí o ba ja ẹ̀mí rẹ lógun tí ó sì borí rẹ nígbà tí ìbínú rẹ bá n le; torí pé eyi n tọka si ikapa rẹ lori ẹmi ara rẹ ati ibori èṣù.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun sùúrù ati ìdarí ẹ̀mí nígbà ìbínú, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ rere ti Isilaamu ṣe wa ni ojúkòkòrò si.

Jija ẹ̀mí ni ogun nígbà ìbínú le koko ju jija ọ̀tá ni ogun lọ.

Isilaamu yi agbọye agbára ni asiko aimọkan padà si awọn iwa alapọn-ọnle, èèyàn ti o ni agbara ju ni ẹni tí ó ni ikapa ìjánu ẹ̀mí ara rẹ.

Jijina si ìbínú; tori ìnira ti o maa n fa fun ènìyàn kọ̀ọ̀kan ati àwùjọ.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin