“Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ

“Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ki o yaa maa ṣe apọnle aládùúgbò rẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa ṣe apọnle àlejò rẹ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ti ẹrú ti o gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ti o maa padà si ti wọn si maa san an ni ẹsan iṣẹ rẹ nibẹ, igbagbọ rẹ maa ṣe e ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe àwọn nǹkan yii: Akọkọ: Ọ̀rọ̀ dáadáa: Bii gbólóhùn SUBHAANALLAH ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati pipaṣẹ dáadáa, ati kikọ ibajẹ, ati ṣíṣe àtúnṣe láàárín àwọn èèyàn, ti ko ba wa ṣe e, ki o yaa dakẹ, ki o si ma fi suta kan èèyàn, ki o si ṣọ ahọ́n rẹ. Ìkejì: Ṣíṣe apọnle aládùúgbò: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn, ati ki èèyàn si ma fi suta kan an. Ikẹta: Ṣíṣe apọnle àlejò ti n bọ láti ṣe abẹwo rẹ: Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dáadáa, ati fífún un ní oúnjẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

فوائد الحديث

Gbigba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn jẹ́ ìpìlẹ̀ fun gbogbo oore, o si maa n jẹ ki oore wu èèyàn láti ṣe.

Ikilọ kuro nibi awọn ìpalára ti ahọ́n maa n fà.

Ẹsin Isilaamu, ẹsin ìfẹ́ ati apọnle ni.

Awọn iroyin yii wa ninu awọn ẹka igbagbọ, ati ninu awọn ẹkọ ti a maa n yìn.

Apọju ọ̀rọ̀ le wọ́ èèyàn lọ sibi nnkan ti a korira tabi nnkan eewọ, ọlà si n bẹ nibi ki èèyàn ma sọ̀rọ̀ àyàfi nibi dáadáa.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin