“Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”

“Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki a ma maa kirun ni ile, ti yoo fi wa da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ.

فوائد الحديث

Ṣiṣe pipọ ni ijọsin ni ohun ti a fẹ ati kiki irun akigbọrẹ ninu ile.

Irun kiki ko lẹtọọ ni awọn iboji; nitori pe o jẹ ọna kan ninu awọn ọna ti wọn maa n gba lati ṣe ẹbọ ati kikọja aala nipa awọn ti wọn wa nibẹ, yatọ si irun ti a maa n ki si oku lara.

Kikọ kuro nibi kiki irun nibi awọn sàréè fi ẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn saabe, nitori idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ lati jẹ ki awọn ile da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ.

التصنيفات

Ọla ti n bẹ fun àwọn suura ati awọn aaya