Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan

Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan

Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin, ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun, ati pe iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo ki wọn si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, Ati pe iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ. Lẹyin naa Mu’aadh sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ mi ko nii fun awọn eniyan ni iro ki wọn le dunnu pẹlu ọla yìí? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ fun un ni ti ipaya ki wọn maa gbe ara le e.

فوائد الحديث

Alaye iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O ṣe e ni dandan lori awọn ẹrusin Rẹ, oun ni ki wọn maa jọsin fun Un, ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ.

Alaye iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O ṣe e ni dandan fun ara Rẹ ni ti ọla lati ọdọ Rẹ ati idẹra, oun ni ki O mu wọn wọ alujanna, ki o si ma fi iya jẹ wọn.

Iro idunnu ti o tobi n bẹ nibẹ fun awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ pe ìkángun wọn ni wiwọ alujanna.

Mu’aadh sọ hadisi yii ṣíwájú iku rẹ; ni ti ipaya kiko si inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.

Akiyesi lori aima fọn apakan awọn hadisi ka lọdọ awọn eniyan kan ni ti ibẹru lori ẹni ti ko ni imọ nipa ìtumọ̀ rẹ; ìyẹn nibi nnkan ti ko si iṣẹ lábẹ́ rẹ tabi ìjìyà kan ninu awọn ìjìyà Sharia.

Àwọn ẹlẹṣẹ nínú awọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo wa lábẹ́ fifẹ Ọlọhun, ti O ba fẹ yoo fi iya jẹ wọn ti O ba si fẹ yoo fori jin wọn, lẹyin naa ìkángun wọn maa jẹ alujanna.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah, Taohiid ti uluuhiyyah, Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo