“Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”

“Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”

Láti ọ̀dọ̀ Toowus, o sọ pe: Mo ba àwọn èèyàn kan nínú àwọn saabe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wọn maa n sọ pe gbogbo nǹkan pẹ̀lú kadara ni, o sọ pe: Mo gbọ ti Abdullah ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- ti n sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan pẹ̀lú kádàrá ni; Titi dórí ikagara, oun naa ni: Gbígbé ohun ti o jẹ dandan láti ṣe jù silẹ ati dídá ìgbà si i ati lilọ ọ lára tayọ asiko rẹ, ninu ọrọ ayé ati ti alukiyaamọ. Ati ijafafa, oun naa ni: Ijafafa ati ọgbọ́n nípa àwọn àlámọ̀rí ayé àti alukiyaamọ. Ati pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ti kádàrá ikagara ati ijafafa ati gbogbo nǹkan, nǹkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ ni ayé àyàfi ki o ti ṣaaju ninu imọ Ọlọhun ati fifẹ Rẹ.

فوائد الحديث

Àlàyé adisọkan àwọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- nibi kádàrá.

Gbogbo nnkan n ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú kádàrá Ọlọhun ti o fi dórí ikagara ati ijafafa.

Ifi ẹri òdodo múlẹ̀ ati iṣọra àwọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- nibi gbígbé ọ̀rọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).

Igbagbọ ninu gbogbo kádàrá, oore rẹ ni ati aburú rẹ.

التصنيفات

Nini igbagbọ si idajọ Ọlọhun ati ipebubu [Rẹ], Awọn ipo idajọ ati kadara