“Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn

“Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14)”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba gbagbe lati ki eyikeyii irun kan ti a ṣe e ni ọran-anyan titi asiko fi lọ, o jẹ dandan fun un lati tete ki o si yara lọ san an ni kete ti o ba ti ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ ati bibo fun ẹṣẹ gbigbe e ju silẹ afi ki Musulumi naa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, Ọlọhun sọ ninu iwe Rẹ Alapọn-ọnle pé: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14), o n túmọ̀ si pe: Ki o si ki irun ti a gbagbe nigba ti o ba ti ranti rẹ.

فوائد الحديث

Alaye pataki irun ati aimaṣe ọlẹ nibi kiki rẹ ati sisan an padà.

Lilọ irun lara tayọ asiko rẹ ko lẹtoọ ni ti mọọmọ laini awijare.

Jijẹ dandan sisan irun pada fun ẹni ti o ba gbagbe ti o ba ti ranti ati ẹni ti o sun ti o ba ti ji.

Jijẹ dandan sisan awọn irun pada ni yara yara koda ko jẹ awọn asiko ti a ṣe kiki irun ni eewọ nibẹ.

التصنيفات

Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, Awọn àṣìṣe awọn olukirun