Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo

Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo

Lati ọdọ Abu Qataada as-Sulamiyy – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe ẹni ti o ba wa si masalaasi ti o si wọle sibẹ ni eyikeyii asiko, ati fun èyíkéyìí erongba, ni ojukokoro lati ki rakaah meji siwaju ki o to jokoo, ati pe awọn mejeeji ni rakaah meji kiki masalaasi.

فوائد الحديث

Ninifẹẹ si kiki irun rakaa meji ni ti kiki masalaasi siwaju ijokoo.

Aṣẹ yii wa fun ẹni ti o ba gbero lati jokoo, nitori naa ẹni ti o ba wọ masalaasi ti o si jade siwaju ki o to jokoo, aṣẹ yẹn o ko o sinu.

Ti ẹni ti o fẹ kirun ba wọ masalaasi ti awọn eeyan si n kirun lọwọ, ti o wa darapọ mọ wọn nibẹ, ko bukaata si ki o ki rakaa meji naa mọ.

التصنيفات

Irun akigbọrẹ, Awọn idajọ awọn mọsalasi