Awọn ìrun wakati maraarun, Irun Jimọ sí Jimọ, Ramadan sí Ramadan, ó máa n pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí n bẹ laarin wọn rẹ́ ni, tí eniyan bá ti jìnnà sí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá

Awọn ìrun wakati maraarun, Irun Jimọ sí Jimọ, Ramadan sí Ramadan, ó máa n pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí n bẹ laarin wọn rẹ́ ni, tí eniyan bá ti jìnnà sí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá

Lati ọdọ Abu Huraira - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - máa n sọ pé: "Awọn ìrun wakati maraarun, Irun Jimọ sí Jimọ, Ramadan sí Ramadan, ó máa n pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí n bẹ laarin wọn rẹ́ ni, tí eniyan bá ti jìnnà sí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fun wa pé dajudaju awọn ìrun ọ̀ranyàn wakati maraarun lojoojumọ, irun Jimọ ni gbogbo ọsẹ, gbigba aawẹ oṣu Ramadan ni gbogbo ọdun, ó máa n pa awọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké tí eniyan bá dá laarin wọn rẹ́ ni, pẹlu majẹmu pé kí eniyan jìnnà si awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá, àmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá, gẹgẹ bii ṣìná àti ọtí mímu, wọn kò nii pa a rẹ́ àyàfi kí eniyan túúbá kúrò níbẹ̀ kó sì ronúpìwàdà.

فوائد الحديث

Awọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn, kéékèèké n bẹ ninu wọn, ńlánlá naa sì n bẹ ninu wọn.

Majẹmu pípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké rẹ́ ni jíjìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlánlá.

Awọn ẹ̀ṣẹ̀ nlanla ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti ijiya wà lori rẹ̀ ni aye, tabi ileri ijiya tabi ibinu Ọlọhun wà lori rẹ̀ ní ọ̀run, tàbí ìdẹ́rùbani wà lori rẹ̀, tabi ibidandan Ọlọhun wà lori ẹnití ó ṣe e, gẹgẹ bii ṣìná àti ọtí mímu.

التصنيفات

Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ, Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ rere, Ọla ti o n bẹ fun irun