Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna

Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tọrọ iyẹpẹrẹ ati idojuti titi o fi da gẹgẹ bii pe o ki imu rẹ bọ inu erupẹ- o paara rẹ lẹẹmẹta- wọn wa bi i leere pé: Tani ẹni yii irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ti o ṣepe fún? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba awọn obi rẹ mejeeji nigba ogbo- ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji-, ti wọn ko wa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ; ìyẹn maa ri bẹẹ torí aiṣe daadaa si awọn mejeeji ati ṣiṣẹ awọn mejeeji.

فوائد الحديث

Ijẹ dandan ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji ati pe o wa ninu awọn okunfa wiwọnu alujanna, pataki julọ nígbà ogbo wọn ati lilẹ wọn.

Ṣiṣẹ awọn obi mejeeji wa ninu awọn ẹṣẹ ńlá.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun ṣiṣe daadaa si awọn obi mejeeji