Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ

Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ

Lati ọdọ Abu Dardā'i - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ».

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ni wọn gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju nkan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ninu awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ni iwa daadaa, ati pe ìyẹn n bẹ pẹlu titu oju ka, ati kika ṣuta kuro, ati ṣiṣe daadaa. Ati pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga korira ẹni ti ko dara nibi iṣe rẹ ati ọrọ rẹ, ẹni ti maa n fi ahọn rẹ sọ ibajẹ.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun iwa daadaa; nitori pe o maa n jogun ifẹ Ọlọhun fun ẹni ti ba n ṣe e, pẹlu ifẹ awọn ẹru Rẹ, ati pe oun ni o tobi julọ ninu nkan ti wọn o wọn ni ọjọ igbedide.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin, Awọn ẹkọ ọrọ sísọ ati didakẹ