“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”

“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣeni lojukokoro lati maa da ẹbí pọ pẹ̀lú abẹwo ati apọnle ti ara ati ti owó, ati nǹkan ti o yatọ si i, oun si tun ni okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn.

فوائد الحديث

Ar-Rọhim ni àwọn mọlẹbi ni igun ti bàbá ati iya, bi o ba ṣe sunmọ si naa ni o ṣe ni ẹtọ láti da a pọ̀ tó.

Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ ni, ẹni tí ó bá da ẹbí rẹ pọ pẹ̀lú dáadáa, Ọlọhun maa da a pọ̀ nibi ọjọ́-orí rẹ ati arisiki rẹ.

Dida ẹbí pọ jẹ okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò ti èèyàn maa lò laye ati arisiki ti ni gbèdéke, ṣùgbọ́n o tun le jẹ ìbùkún nibi arisiki ati ọjọ́-orí, o maa wa fi ìgbésí ayé rẹ ṣe nǹkan ti o maa pọ ti o si maa ṣe àǹfààní ju nǹkan ti ẹlòmíràn maa ṣe lọ, àwọn kan sọ pé alekun arisiki ati ọjọ́-orí naa maa jẹ alekun gidi. Ọlọhun ni O ni imọ julọ.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ rere