“Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti o ba jẹun ti o wa dúpẹ́ lori rẹ, tabi ti o mu ti o wa dupẹ lórí rẹ”

“Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti o ba jẹun ti o wa dúpẹ́ lori rẹ, tabi ti o mu ti o wa dupẹ lórí rẹ”

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti o ba jẹun ti o wa dúpẹ́ lori rẹ, tabi ti o mu ti o wa dupẹ lórí rẹ”

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe idupẹ ẹrú fun Olúwa rẹ lórí ọla Rẹ ati awọn idẹra Rẹ wa ninu awọn alamọri ti maa n fa iyọnu Ọlọhun; ti o ba jẹun, o maa sọ pé: ALHAMDULILLAAH, ti o ba mu, o maa sọ pé: ALHAMDULILLAAH.

فوائد الحديث

Títa ọrẹ Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, O fúnni ni arisiki, O si yọnu si idupẹ.

Eeyan le ri iyọnu Ọlọhun ni ọ̀nà ti o rọrun jùlọ, gẹgẹ bii ṣíṣe ALHAMDULILLAAH lẹ́yìn jijẹ ati mimu.

Ninu ẹkọ oúnjẹ ati nǹkan mimu ni: Idupẹ fun Ọlọhun lẹyin jijẹ ati mimu.

التصنيفات

Awọn ẹkọ jijẹ ati mimu