Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ

Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ

Lati ọdọ Umar ọmọ Abu Salama- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo jẹ ọmọdekunrin ni abẹ itọju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ọwọ mi o si duro si oju kan ninu abọ, ni Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun mi pé: «Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ» Ìyẹn o wa yẹ ni ìṣesí ounjẹ mii lẹyin igba naa.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Umar ọmọ Abu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -, ọmọ iyawo anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n ṣe ummu salamah - ki Ọlọhun yọnu si i - o si wa ni abẹ itọju rẹ ati amojuto rẹ -, n sọ pé òun jẹ ẹni ti o maa n gbe ọwọ rẹ kaakiri ẹgbẹẹgbẹ abọ ni asiko ounjẹ, nitori naa Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa kọ ọ ni awọn ẹkọ mẹta ninu awọn ẹkọ jijẹ: Alakọkọọ rẹ ni: Gbólóhùn "BismilLah" ni ibẹrẹ ounjẹ. Ati pe ẹlẹẹkeji ni: jíjẹ ounjẹ pẹlu ọwọ ọtun. Ati pe ẹlẹẹkẹta rẹ ni: Jijẹ nibi ẹgbẹ ti o ba sunmọ ọn ninu oúnjẹ.

فوائد الحديث

Ninu awọn ẹkọ jíjẹ ati mimu ni didarukọ Ọlọhun ni ibẹrẹ rẹ.

Kikọ awọn ọmọde ni awọn ẹkọ, agaga julọ ẹni ti o ba wa ni abẹ itọju eeyan.

Ṣiṣe idẹkun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati gbigba aaye igbaaya rẹ nibi fifi imọ mọ awọn ọmọde ati kikọ wọn ni ẹkọ.

Ninu awọn ẹkọ ounjẹ jíjẹ ni imaa jẹ ninu nkan ti o ba sunmọ eeyan, ayaafi ti o ba jẹ awọn iran orisirisi, nigba naa o le mu ninu rẹ.

Idunnimọ awọn saabe pẹlu nkan ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ba fi kọ wọn, wọn mu iyẹn jade lati ibi ọ̀rọ̀ Umar ti o sọ pe: Ìṣesí mi o wa yẹ lori ìyẹn lẹyin igba naa.

التصنيفات

Awọn ẹkọ jijẹ ati mimu