إعدادات العرض
“Ẹ fi àwọn ìpín ogún (fara’id) fún àwọn tí ó tọ si, oun tí ó bá ṣẹkù lẹ́yìn náà, kó lọ fún ọkùnrin tí ó sunmọ́ (oku) jù lọ (ní ìbátan)
“Ẹ fi àwọn ìpín ogún (fara’id) fún àwọn tí ó tọ si, oun tí ó bá ṣẹkù lẹ́yìn náà, kó lọ fún ọkùnrin tí ó sunmọ́ (oku) jù lọ (ní ìbátan)
Láti ọdọ Ibnu Abbas -kí Ọlọhun o yọnu sí awọn méjèjì- láti ọdọ Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ o máa ba a, o s'ọpe: “Ẹ fi àwọn ìpín ogún (fara’id) fún àwọn tí ó tọ si, oun tí ó bá ṣẹkù lẹ́yìn náà, kó lọ fún ọkùnrin tí ó sunmọ́ (oku) jù lọ (ní ìbátan)".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Indonesia Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Hausa Português Русский Македонски नेपाली دری پښتو ગુજરાતી ភាសាខ្មែរ Shqip Українська Čeština Српски Kurdî ქართული Magyar ਪੰਜਾਬੀ Kiswahili ಕನ್ನಡ മലയാളം тоҷикӣ kmr සිංහල తెలుగు O‘zbek தமிழ் Tiếng Việt ไทย Deutsch Malagasy Nederlandsالشرح
Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o maa ba- n paṣẹ fún àwọn tí ń ṣàkóso ogún pínpín pé kí wọ́n pín (ogun ti oku fi silẹ) fún àwọn tí ó tọ si, ni ìpín ti o ṣe dede ofin (shari'a), gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun ṣe fẹ́. Nítorí náà, a máa fún àwọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun ní ipin wọn, tí awọn ìpín naa si jẹ: ìdáméjì ninu ida mẹta ogún, idankan idamẹta, idafa, ìdajì, idamẹrin, ati idamejọ ogún, ohun tí o ba wa sẹku lẹyin naa, a o fún ẹni tí ó sunmọ́ oku jù lọ ninu awọn ọkùnrin, ti wọ́n sì ń pè wọn ní Al-‘asabah (àwọn ìbátan ọkùnrin tí ń jogún ohun tí ó sẹkù lẹyin ti a pin ogun tan).فوائد الحديث
Hadithi yii jẹ ìpìlẹ lori ilana ogún pínpín.
Ati pé pínpín ogún a máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífún àwọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun (Ahlu Al-fara’id) ní ipin wọn.
Àti pé ohun tí o ba sẹku (ninu ogun) lẹyin igba ti àwọn onípin ba ti gba ipin wọn tan yiò máa jẹ tí awọ̀n Al-Asabah (àwọn ìbátan ọkùnrin tí ń jogún ohun tí ó sẹkù lẹyin ti a pin ogun tan).
Títi awọn tí o sunmọ òkú jùlọ síwájú ni tẹle ntẹle, nitori na Al-Aasibu ti o jina -gẹgẹ bí ọmọiya bàbá òkú- ko ni jẹ ogun lopin igba ti Al-Aasibu ti o sunmọ ba wa gẹgẹ bí Bàbá Oku.
Àti pé kòni si ogún kankan fún Al-Aasibu ti awọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun ba ti kárí gbogbo ogún tí o wa nlẹ tán, iyẹn nipe tí kò ba sẹku nkankan mọ.
التصنيفات
Awọn ti wọn jẹ ogun ti ko ni odiwọn