“Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn”

“Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn”

Láti ọ̀dọ̀ Khaolat ọmọbìnrin Hakiim As-Sulamiyyah, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ ìjọ rẹ sọ́nà lọ sibi ìdìrọ̀mọ́ ati ìsádi ti o maa ṣe àǹfààní ti gbogbo nnkan ti a n ṣọ́ra fun ti èèyàn n bẹ̀rù maa lọ pẹ̀lú rẹ nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan lórí ilẹ̀, boya o wa ni ìrìn-àjò ni, tabi ìjáde ìgbafẹ́, tabi ohun ti o yatọ si ìyẹn: Pẹ̀lú pe ki o dìrọ̀ mọ́ ki o si sádi àwọn gbólóhùn Ọlọhun ti o pe nibi ọla rẹ ati ibukun rẹ ati àǹfààní rẹ, eyi ti o la kuro nibi gbogbo àléébù, níbi aburu gbogbo ẹ̀dá ti o ni aburu lára, ọkàn rẹ maa wa balẹ ni ààyè yẹn nibi gbogbo nnkan ti o ba le ṣe e ni suta lópin ìgbà tí o ba ṣi wa nibẹ.

فوائد الحديث

Wiwa iṣọra ìjọsìn ni, oun naa ni eyi ti o ba jẹ pẹlu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, tabi awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ.

Ìní-ẹ̀tọ́ wiwa iṣọra pẹlu ọrọ Ọlọhun; torí pé o jẹ ọkan ninu awọn ìròyìn Rẹ, yatọ si ìwá-ìṣọ́ra pẹlu èyíkéyìí ẹ̀dá, ẹbọ ni ìyẹn.

Ọla ti n bẹ fun adua yii ati alubarika rẹ.

Wiwa ààbò pẹ̀lú àwọn iranti Ọlọhun jẹ okùnfà láti ṣọ́ ẹrú kúrò nibi aburú.

Bíba ìwá-ìṣọ́ra pẹ̀lú ohun ti o yatọ si Ọlọhun jẹ́, bii alujannu, ati awọn opidan, ati awọn ẹni èké, ati awọn mìíràn.

Adua yii jẹ nnkan ti o ba sharia mu fun ẹni tí ó ba sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan ni ilé tabi ni ìrìn-àjò.

التصنيفات

Awọn iranti fun àlámọ̀rí ti wọn ja wa