Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni?

Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni?

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? Ni ẹẹmẹta. O sọ pe: bẹẹni, Anabi sọ pe Dajudaju ìyẹn maa pa àwọn ẹṣẹ yẹn rẹ.

[O ni alaafia] [Abu Yahlaa ati Tọbarọọniy ati Ad-Diyaau Al-Makdisiy ni wọn gba a wa]

الشرح

Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju mo ti da gbogbo ẹṣẹ, ti mi ko fi ẹṣẹ kekere tabi ńlá kalẹ afi ki n ti ṣe e, njẹ wọn maa forí jin mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? O paara rẹ ni ẹẹmẹta, O da a lohun pe: Bẹẹni mo n jẹrii, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun un ati pipa awọn aburu rẹ̀ rẹ́, ati pe ironupiwada maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.

فوائد الحديث

Titobi ijẹrii mejeeji ati titẹṣuwọn rẹ lori awọn ẹṣẹ fun ẹni ti o ba sọ ọ lododo lati inu ọkan rẹ.

Isilaamu maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.

Ironupiwada ododo maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.

Pipaara nnkan ninu idanilẹkọọ wa ninu imọna Anabi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).

Ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji, ati pe mejeeji jẹ okunfa fun igbala kuro nibi ṣíṣe gbere ninu ina.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo