إعدادات العرض
(Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem)
(Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem)
Lati ọdọ Az-Zubair ọmọ Al-Awwaam, o sọ pe: Nigba ti (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) sọkalẹ (At-Takathur: 8), Az-Zubair sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ, dajudaju mejeeji ni dudu meji, eso dabinu ati omi? O sọ pe: “Oun naa ni o maa jẹ”.
[O daa] [Tirmiziy ati Ibnu Maajah ni wọn gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली മലയാളം Bosanski Italiano ಕನ್ನಡ Kurdî Oromoo Română Shqip Soomaali Српски Українська Wolof Tagalog Moore Malagasy தமிழ் Azərbaycanالشرح
Nigba ti ayah sọkalẹ: (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) o n túmọ̀ si pe: Wọn maa pada beere lọwọ wọn nipa idupẹ lori nnkan ti Ọlọhun ṣe ni idẹra le wọn lori ninu awọn idẹra, Az-Zubair ọmọ Al-‘Awwam- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ? Dajudaju idẹra mejeeji ko kii ṣe nnkan ti wọn le bukaata si ibeere ati pe mejeeji ni eso dabinu ati omi! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: Dajudaju wọn maa bi yin leere nipa idẹra pẹlu isẹsi yii ti ẹ wa nibẹ yìí, nitori pe mejeeji jẹ idẹra nla meji ninu awọn idẹra Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.فوائد الحديث
Ikanpamọ idupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn idẹra.
Idẹra, ninu nǹkan ti wọn maa bèèrè nipa rẹ lọ́wọ́ ẹrú ni Ọjọ́ Àjíǹde ni, o kéré ni tabi o pọ.