إعدادات العرض
Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun
Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun».
[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली മലയാളം Bosanski Italiano ಕನ್ನಡ Kurdî Oromoo Română Soomaali Shqip Српски Українська Wolof Tagalog Moore Malagasy தமிழ் Azərbaycan فارسی ქართული 中文 Magyar Portuguêsالشرح
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ti nkankan ba n ru ninu iku ẹni ti n kirun, ti ko wa mọ boya nkan jade tabi nkankan o jade? Ko gbọdọ kuro ni ori irun, ko si gbọdọ ja a lati lọ tun aluwala ṣe, titi ti yio fi ri bibẹ ẹgbin ni aridaju eleyii ti o le ba aluwala jẹ; pẹlu pe ki o gbọ didun iso, tabi ki o gbọ oorun; tori pe dajudaju nkan ti a ti mọ amọdaju rẹ ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe oun ti mọ amọdaju imọra, ti ẹgbin si jẹ nkan ti n ṣe iyemeji ninu rẹ.فوائد الحديث
Hadīth yii ipilẹ kan ni ninu awọn ipilẹ Isilaamu, o tun jẹ òfin kan ninu awọn ofin agbọye ẹsin, oun ni pe: Dajudaju amọdaju ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe ipilẹ ni wiwa nkan ti o n bẹ lori ohun ti o n bẹ lori rẹ, titi ti nkan ti o yatọ si iyẹn fi maa daju.
Iyemeji o ki n lapa nibi imọra, ati pe ẹni ti n kirun si wa lori imọra rẹ lopin igba ti ko ba tii ni amọdaju ẹgbin.