إعدادات العرض
“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”
“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”
Lati ọdọ Saalim ọmọ Abul Jahd, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pé: Ìbá ṣe pé mo ti kírun kí n sì sinmi, bí ẹni pé wọ́n dá a lẹ́bi fún ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.
[O ni alaafia] [Abu Daud ni o gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली മലയാളം తెలుగు Bosanski Italiano ಕನ್ನಡ Kurdî Oromoo Română Soomaali Shqip Српски Українська Wolof Tagalogالشرح
Arakunrin kan ninu awọn saabe sọ pe: Ìbá ṣe pé mo ti kírun ni, kí n sì sinmi, ó dà bíi pé àwọn tó wà láyìíká rẹ̀ dá a lẹ́bi lórí ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Irẹ Bilal! Pe irun, ki o si gbe e dúró; ki a le sinmi pẹlu rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ ni jẹẹjẹ, ati isinmi fun ẹmi ati ọkan.فوائد الحديث
Isinmi ọkan maa n wa pẹlu irun kiki; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
Titako ẹni ti o pa ijọsin tì.
Ẹni ti o ba pe nnkan ti o jẹ dandan fun un, ti o si mọ ọrun rẹ kúrò nibẹ, isinmi maa ṣẹlẹ̀ si i pẹlu rẹ ati níní ìmọ̀lára ifayabalẹ.