Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ

Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ

Lati ọdọ ọmọ umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní oun gbọ lẹnu ọkunrin kan ti n sọ pe: Rara o, oun fi Kaabah búra, ọmọ umar wa sọ fun un pe: A kò gbọdọ̀ fi nnkan tó yatọ si Ọlọhun Allah búra, tori dajudaju emi gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pe: "Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ."

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo pé ẹnikẹni tí ó bá fi nkan miran búra yatọ si Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, onitọhun ti ṣaigbagbọ si Ọlọhun, tabi ka ní ó ti ṣẹbọ pẹlu Rẹ̀; nítorí pé ìbúra ní í ṣe pẹ̀lú ìgbétítóbi fún nkan tí a fi búra, títóbi sì jẹ́ ti Ọlọ́hun Allah nìkan ṣoṣo; nitori naa, a kò gbọdọ̀ bura pẹlu nkankan ayafi Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, Mimọ ni fun Un, Ati pé ìbúra yii wà ninu ẹbọ kekere; ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó búra bá fi gbé títóbi fun nkan tó fi bura gẹgẹ bii ìgbétítóbi fún Ọlọ́hun Allah tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ; nigba naa, ó ti wà ninu ẹbọ nla niyẹn.

فوائد الحديث

Dajudaju fífi ibura gbé titobi fún nkan jẹ́ ẹ̀tọ́ fún Ọlọhun Allah, mimọ ni fun Un, nitori naa a kò gbọdọ búra pẹlu nkankan ayafi Ọlọhun ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀.

Ìtaraṣàṣà awọn Sahabe lori pipaṣẹ rere ati kikọ aburu, paapaa julọ tí aburu naa ba nii ṣe pẹlu ẹbọ tabi aigbagbọ.

التصنيفات

Ida ọrọgun pọ mọ Ọlọhun