“Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”

“Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”

Láti ọ̀dọ̀ Mah’qil ọmọ Yasaar Al-Muzaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni kọọkan ti Ọlọhun ba fi ṣe olori fun awọn èèyàn, boya o jẹ àṣẹ ti gbogbogboo ni gẹgẹ bii alaṣẹ ìlú, tàbí àṣẹ ti kii ṣe ti gbogbogboo, gẹgẹ bii ọkùnrin ninu ile rẹ, ati obinrin ninu ile rẹ, ti o wa ṣe ohun ti o kù díẹ̀ káàtó nibi ẹ̀tọ́ àwọn ti n bẹ ni abẹ rẹ, o tun rẹ́ wọn jẹ, ko si gba wọn ni imọran, o wa fi iwọ̀ wọn ti ẹsin ati ayé ráre, o ti ni ẹ̀tọ́ si ìjìyà ti o le koko yìí.

فوائد الحديث

Àdéhùn ìjìyà yii kii ṣe ti imaamu agba nìkan ati àwọn aṣojú rẹ, bi ko ṣe pe o kari gbogbo ẹni tí Ọlọhun ba ni ki o maa darí àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ.

Ohun ti o jẹ dandan fun ẹni ti Ọlọhun ba ni ki o jẹ alaṣẹ fun nǹkan kan ninu àlámọ̀rí àwọn Musulumi ni ki o gba wọn ni ìmọ̀ràn, ki o si gbìyànjú láti pe agbafipamọ, ki o si ṣọ́ra fun ìjàǹbá.

Titobi ojúṣe gbogbo ẹni tí o ba jẹ alaṣẹ gbogbogboo tabi ti ara ẹni, o tobi ni tabi o kere.

التصنيفات

Òṣèlú ti Sharia