“Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́

“Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́

Láti ọ̀dọ̀ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́”, o sọ pe: Lẹ́yìn náà ni o ka: “{Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102]”

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kúrò nibi itẹsiwaju ninu abosi dídá ẹṣẹ ati ṣíṣe ẹbọ, ati ṣíṣe abosi fun awọn èèyàn nibi ẹ̀tọ́ wọn; torí pé Ọlọhun maa n lọ alabosi lára, O si maa n jẹ ki ẹmi rẹ o gùn ti dúkìá rẹ si tun maa pọ̀, ko waa ni kanju fi ìyà jẹ ẹ, ti ko ba wa ronupiwada, O maa mu u ti ko si nii fi i sílẹ̀ fun abosi rẹ ti o pọ. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102].

فوائد الحديث

O di dandan fun onilaakaye ki o tètè yara ronupiwada, ki o si ma fi aya balẹ nibi ète Ọlọhun ti o ba ṣi wa lori àbòsí.

Bi Ọlọhun ṣe n lọ àwọn alabosi lara ti ko tete fi iya jẹ wọn lati dẹ wọn lẹ́kẹ ni ati lati ṣe adipele iya wọn ti wọn ko ba ronupiwada.

Abosi wa ninu awọn okùnfà ìyà Ọlọhun fun awọn èèyàn.

Ti Ọlọhun ba pa abúlé kan run, àwọn ẹni rere le wa ninu ẹ, àwọn wọ̀nyí wọn maa gbe wọn dide ni Ọjọ́ Àjíǹde lori nǹkan ti wọn ku le lori ninu daadaa, ki iya naa o ko wọn sinu ko ni wọn lara.

التصنيفات

Adisọkan, Taohiid ti àwọn orúkọ ati awọn iroyin, Awọn iwa eebu