“Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun”

“Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun”

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé adehun iya ti o le koko to wa lori pe dajudaju ẹni ti o ba pa ẹni ti a gba adehun lọwọ rẹ- oun ni ẹni ti o wọ ilẹ̀ Isilaamu ninu awọn alaigbagbọ pẹlu adehun ati ifọkanbalẹ- pe ẹni naa ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ maa jẹ ijiina irin ogoji ọdun.

فوائد الحديث

Ṣíṣe leewọ pipa Al-Mu’aahad ati Adh-dhimmiyy ati Al-Mustahman ninu awọn alaigbagbọ, ati pe o jẹ ẹṣẹ nla ninu awọn ẹṣẹ ńláńlá.

Al-Mu’aahad ni: Ẹni ti wọn gba adehun lọwọ rẹ ninu awọn alaigbagbọ ti o si n gbe ni ilu rẹ ti ko gbe ogun ti awọn Musulumi ti awọn naa ko gbe ogun ti i, Adh-dhimmiyy ni: Ẹni ti o sọ ilẹ̀ awọn Musulumi di ilu ti o si n san ìsákọ́lẹ̀, Al-Mustahman ni: Ẹni ti o wọ inu ilẹ̀ awọn Musulumi pẹlu adehun ati ifọkanbalẹ fun asiko kan pàtó.

Ikilọ kuro nibi jijanba awọn adehun pẹlu awọn ti wọn ko kii ṣe Musulumi.

التصنيفات

‏Awọn idajọ awọn ti wọn gbe ilu Isilaamu ti wọn o ki n ṣe musulumi