Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)

Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)

Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir Al-Juhaniy - ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ikọ kan wa ba a, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn ti o ka ọwọ duro fun ẹnikan, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan o si fi eleyii silẹ? O sọ pe: «Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ», ni o (arakunrin yẹn) wa ti ọwọ rẹ wolẹ ti o si fa a ja, nigba naa ni o (Anabi) wa gba ọwọ adehun (ibura) rẹ, ni o wa sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)».

[O daa] [Ahmad ni o gba a wa]

الشرح

Awọn ikọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti onka wọn sì jẹ mẹwaa, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn lori Isilaamu ati itẹle aṣẹ, ti ko si gba ọwọ adehun (ibura) ti ẹni kẹwàá, nigba ti wọn wa beere nipa idi ìyẹn o sọ - ki ikẹ ati ọla maa ba a - pe: Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ, oun naa ni nkan ti wọn maa n de tabi ti wọn maa n sokọ latara ilẹkẹ ati nkan miran yatọ si i lati fi ti ojukoju tabi inira danu. Ni arakunrin naa wa ti ọwọ rẹ bọ aaye ti agbekọ naa wa ti o si ja a ti o si bọra kuro nibẹ, nigba naa ni o gba ọwọ adehun pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o (Anabi) wa sọ lẹni ti n kilọ kuro nibi agbekọ ti o si n ṣe alaye idajọ rẹ pe: Ẹni ti o ba so agbekọ ó ti ṣe ẹbọ (mu orogun mọ Ọlọhun)”

فوائد الحديث

Ẹni ti o ba gbe ara le nkan ti o yatọ si Ọlọhun, Ọlọhun a ba a lo pẹlu idakeji erongba rẹ.

Nini adisọkan pe dajudaju siso agbekọ okunfa fun titi aburu ati ojukoju danu ni jẹ ẹbọ kékeré, ṣugbọn ti o ba ni adisọkan pe o le se anfaani fúnra rẹ, ẹbọ ti o tobi niyẹn.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah