إعدادات العرض
Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa
Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».
[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands සිංහල தமிழ் دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली Malagasy Italiano or ಕನ್ನಡ Oromoo Română Soomaali Српски Wolof Українська Moore Azərbaycan ქართული Magyarالشرح
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye pe dajudaju awọn ti wọn maa n kẹ awọn ti wọn yatọ si wọn, Ọba Ajọkẹ aye naa o kẹ wọn pẹlu ikẹ Rẹ ti o kari gbogbo nkan; ní ti ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn). Lẹyin naa ni o wa pa aṣẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu kikẹ gbogbo nkan ti o wa lori ilẹ ni eeyan tabi ẹranko tabi ẹyẹ tabi nkan ti o yatọ si i ninu awọn iran ẹda, ati pe ẹsan iyẹn naa ni ki Ọlọhun kẹ wọn lati oke awọn sanmọ Rẹ.فوائد الحديث
Ẹsin Isilaamu ẹ̀sìn ikẹ ni, ti gbogbo rẹ si duro lori itẹle aṣẹ Ọlọhun ati ṣiṣe daadaa si ẹda.
Ọlọhun – ti O tobi ti O gbọnngbọn - Ọba ti O ni ìròyìn ikẹ lara ni, ati pe Oun – mimọ fun un – ni Ajọkẹ aye Aṣakẹ orun, ti O si maa n mu ikẹ de ọdọ awọn ẹru Rẹ.
Iru iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan ti yio gba, nitori naa awọn ti wọn ba maa n kẹ eeyan Ọlọhun a kẹ awọn naa.