Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi

Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi

Lati ọdọ ‘Aaisha ati Abdullahi ọmọ’Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- wọn sọ pé: Nigba ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pọka iku, o bẹ̀rẹ̀ si nii fi aṣọ nu oju rẹ, ti o ba ti wa di pe ko le mí mọ́ daadaa, o maa ka a kuro loju rẹ, o wa sọ bi o ṣe wa bẹẹ pe: “Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi” ti o n ṣe ikilọ kuro nibi nnkan ti wọn ṣe.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

‘Aaisha ati Ibnu ‘Abbas- ki Ọlọhun yọnu si wọn- n sọ fun wa pé, nigba ti iku de ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o fi egige aṣọ soju rẹ, ti mimi ba ti ṣoro fun un latara awọn irora iku yoo mu u kuro loju rẹ, o wa sọ ninu isẹsi ti o le koko yẹn pé: Ọlọhun ṣẹbi le awọn Juu ati Nasara, O si le wọn jina si ikẹ Rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe wọn kọ mọsalasi lori awọn saare awọn Anabi wọn, bi ko ba ṣe bi alamọri naa ṣe lewu to ni ko nii darukọ rẹ nibi iru aaye yìí, fun idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ fun ijọ rẹ kuro nibi ṣíṣe afijọ iṣe yẹn; nitori pe o wa ninu ìṣe awọn Juu ati Nasara, ati pe nitori pe o jẹ oju ọna kan ti o le múni debi ṣiṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn.

فوائد الحديث

Kikọ kuro nibi mimu awọn saare awọn Anabi ati awọn ẹni rere ni mọsalasi ti wọn maa kirun nibẹ fun Ọlọhun, nitori pe ìyẹn jẹ atẹgun lọ sibi ẹbọ.

Ini akolekan ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati amojuto rẹ gan si imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo ati ibẹru rẹ fun bibabara awọn saare; nitori ìyẹn maa ja si ẹbọ.

Ṣiṣe lẹtọọ ṣiṣẹbi le awọn Juu ati Nasara ati ẹni ti o ba ṣe bii iṣe wọn ninu mimọ nnkan sori awọn saare ati mimu wọn ni mọsalasi.

Mimọ nnkan sori awọn saare wa ninu awọn oju ọna Juu ati Nasara, kikọ kuro nibi fifi ara wé wọn si n bẹ ninu hadiisi náà.

Kiki irun nibẹ tabi si i lara n bẹ ninu mimu awọn saare ni mọsalasi, koda ki wọn ma kọ mọsalasi.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah