Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ

Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ

Lati ọdọ Huzaifah- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ".

[O ni alaafia] [An-Nasaa’i]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki Musulumi maa sọ nibi ọrọ rẹ pé: "Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ", Tabi ohun ti Ọlọhun ati lagbaja ba fẹ; Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe fifẹ Ọlọhun ati erongba rẹ jẹ nnkan ti a tu kalẹ ti ẹnikẹni ko si ba A kẹgbẹ nibẹ, Ati pe o n bẹ nibi lilo harafi waw nibi asopọ naa, imuninimọlara pe ẹnìkan n ba Ọlọhun kẹgbẹ ati ifidọgba láàrin ẹni yẹn ati Ọlọhun. Ṣugbọn yoo maa sọ pé: Ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ, Ki o fi fifẹ ẹru tẹle fifẹ Ọlọhun pẹlu sisọ pe: "Thummo" dipo "Wa", nitori pe "Thummo" n ṣe àǹfààní ki nǹkan wa lẹyin ati lilọra.

فوائد الحديث

Ṣíṣe leewọ sisọ pe: "Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti iwọ naa ba fẹ", ati nnkan ti o jọ ìyẹn ninu awọn gbolohun, ninu nnkan ti asopọ mọ Ọlọhun ń bẹ nibẹ pẹlu lilo harafi waw; nitori pe o wa ninu dida orogun pọ mọ Ọlọhun nibi awọn gbolohun ati awọn ọrọ.

Nini ẹtọ sisọ pe: "Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti o ba fẹ", ati nnkan ti o jọ ìyẹn, ninu nnkan ti asopọ mọ Ọlọhun n bẹ nibẹ pẹlu lilo gbolohun thummo; nitori aisi nnkan ti a n sọra fun nibẹ.

Fifi fifẹ rinlẹ fun Ọlọhun, ati fifi fifẹ rinlẹ fun ẹru, ati pe fifẹ ẹru n tẹle fifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni.

Kikọ kuro nibi fifi ẹda ṣe akẹgbẹ nibi fifẹ Ọlọhun, koda ki o jẹ pẹlu gbolohun.

Ti olusọrọ ba ni adisọkan pe dajudaju fifẹ ẹru da gẹgẹ bii fifẹ Ọlọhun- Ọba ti O gbọnngbọn ti O lágbára- ni ti ṣiṣe deedee rẹ nibi kikari ati titu kalẹ, tabi pe dajudaju ẹru ni fifẹ ti o da duro, òun ni ẹbọ nla, ṣùgbọ́n ti o ba ni adisọkan nnkan ti o yàtọ̀ si ìyẹn; oun ni ẹbọ kekere.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah