ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)

ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Al-Shikhiir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo lọ pẹlu awọn ikọ bani Āmir si ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)».

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Awọn ijọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nigba ti wọn de ọdọ rẹ wọn sọ - ni ẹni ti n yin in - awọn ọrọ eleyii ti o korira rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, Ni wọn wa sọ pe: "Iwọ ni olowo wa", Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun wọn pe: Allāhu ni Olowo. Nitori naa o n bẹ fun Un iyi (isiwaju) ti o pe lori awọn ẹru Rẹ, ati pe awọn ni ẹrusin Rẹ. Ni wọn wa sọ pe: Iwọ ni "ẹni ti o lọla julọ ninu wa" ti o si tun ga jùlọ ni ipo ati iyi ati ẹyẹ. Ati pe iwọ ni "ẹni ti o tobi julọ ninu wa ni ọrọ" ti o tun pọ julọ ni ọrẹ tita ati giga. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tọ́ wọn sọna pe ki wọn máa sọ gbolohun wọn ti wọn ti ba saaba ki wọn o si ma la awọn gbolohun kan bọ ara wọn lọrun, ki esu ma lọ ti wọn lọ si ibi aseju ati ayinju eleyii ti maa n muni ko sinu nkan ti wọn ṣe leewọ ni ẹbọ (imu orogun mọ Ọlọhun) ati awọn atẹgun rẹ.

فوائد الحديث

Titobi ipo Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni ẹmi awọn saabe ati apọnle wọn fún un.

Kikọ kuro ninu ilabọrun nibi awọn ọrọ, ati ṣiṣe iwọntunwọnsi nibi ọrọ

Idaabobo taoheed (mimu Ọlọhun lọkan) kuro nibi nkan ti o le ko aayẹ ba a ninu awọn ọrọ ati awọn iṣe.

Kikọ kuro nibi ikọja aala nibi ẹyin, nítorí pé o wa ninu awọn abawọle shaytaan.

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni asiwaju gbogbo ọmọ Anabi Aadam, ati pe eyi ti o wa ninu hadīth yẹn ninu ọna itẹriba lo wa, ati ni ti ipaya ki wọn ma kọja aala nipa rẹ.

التصنيفات

Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-