Ẹni ti o ba ṣe amọ̀nà lọ sibi oore, o maa ní irú ẹsan ẹni tí ó bá ṣe e

Ẹni ti o ba ṣe amọ̀nà lọ sibi oore, o maa ní irú ẹsan ẹni tí ó bá ṣe e

Láti ọ̀dọ̀ Ibnu Mas’ud Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ọkùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pé: Nǹkan ọ̀gùn mi ti kú, fun mi ni nǹkan ti maa gùn, ni o wa sọ pé: “Mi o ni”, arákùnrin kan wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, maa júwe fun un ẹni tí ó maa fun un ni nǹkan ti o maa gùn, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ẹni ti o ba ṣe amọ̀nà lọ sibi oore, o maa ní irú ẹsan ẹni tí ó bá ṣe e”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Ọkùnrin kan wa sọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: Ràkúnmí mi ti parun, ba mi wa ràkúnmí kan ti maa gun ti o maa gbe mi de ibi ti mo n lọ, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mu àwáwí wa fun un pe oun ko nii nǹkan ti o le gun, arákùnrin kan ti o wa nibẹ wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, maa júwe ẹni tí ó máa fun un ni nǹkan ọ̀gùn fun un, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé alabaakẹgbẹ nibi ẹsan ni fun ẹni ti o ba fun un ni nnkan ọ̀gùn; tori pe oun ni o júwe rẹ fun ẹni tí ó ni bukaata si i.

فوائد الحديث

Ṣiṣenilojukokoro lori ìjúwe lọ sibi oore.

Igbaniyanju lati ṣe rere jẹ ọkan ninu awọn idi fun iṣọkan àwùjọ Musulumi ati pípé rẹ.

Fífẹ̀ ọla Ọlọhun.

Hadiisi naa jẹ òfin kan ti o kari ti gbogbo iṣẹ́ olóore maa ko sinu rẹ.

Ti ọmọniyan ko ba ni ikapa lati ṣe nǹkan ti ẹni tí n tọrọ nǹkan lọdọ rẹ n fẹ́, o maa júwe ẹlòmíràn fun un.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin