Ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, dajudaju iṣẹ rẹ ti bajẹ”

Ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, dajudaju iṣẹ rẹ ti bajẹ”

Lati ọdọ Buroida ọmọ Al-Husoib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ẹ tete maa ki irun Asr, dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, dajudaju iṣẹ rẹ ti bajẹ”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ikilọ kuro nibi ki èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ lọ irun Asr lara tayọ asiko rẹ, ati pe ẹni ti o ba ṣe bẹẹ, iṣẹ rẹ ti bajẹ, o si ti lọ lasan.

فوائد الحديث

Ṣisẹnilojukokoro lori ṣiṣọ irun Asr ni akọkọ asiko rẹ ati titete lọ ki i.

Adehun iya ti o le koko fun ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, ati pe ki èèyàn jẹ ki ó bọ́ ni asiko rẹ tobi ju ki eeyan jẹ ki irun mìíràn bọ́ lọ, oun ni irun aarin ti a ṣa lẹsa ni pato pẹlu aṣẹ ninu ọrọ Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga-: (Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin). (Al-Baqarah: 238).

التصنيفات

Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ