إعدادات العرض
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: “Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”.
[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Español Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe Bosanski සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa മലയാളം తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া Shqip دری Ελληνικά Български Fulfulde Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek नेपाली Moore Kurdî Oromoo Wolof Soomaali Français Tagalog Azərbaycan Українська bm தமிழ் Deutsch ქართული Português mk Magyarالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iṣesi ṣọbẹ-ṣelu pe o da gẹgẹ bii aguntan ti o n ṣe iyemeji ti ko mọ eyi ti o maa tẹle ninu agbo aguntan méjèèjì, O maa lọ ba agbo yii nigba mii, a tun lọ ba omiran nigba mii, Wọn wa ninu idaamu-daabo laaarin igbagbọ ati aigbagbọ, wọn ko si pẹlu awọn olugbagbọ ni ti gbangba ati ni kọkọ, wọn ko si tun si pẹlu awọn alaigbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ, bi ko ṣe pe gbangba wọn wa pẹlu awọn olugbagbọ, ti kọkọ wọn si wa nibi iyemeji ati aisi lojukan, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii.فوائد الحديث
Ninu itọsọna Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni fifi àpẹrẹ lelẹ lati mu awọn ìtumọ̀ sunmọ.
Alaye iṣesi awọn ṣọbẹ-ṣelu bii aisi lojukan ati iyemeji ati aiduroṣinṣin.
Ikilọ nipa iṣesi awọn ṣọbẹ-ṣelu ati ṣiṣeni lojukokoro lori ododo ati ipinnu nibi igbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ.
التصنيفات
Ṣọbẹ-ṣelu