Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo

Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – o sọ pe: Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – silẹ ni erongba ati de e mọlẹ, ni awọn Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ṣé wa maa kọ gbogbo nkan ti o ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni, ti o si jẹ pe ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko ibinu ati iyọnu? Ni mo ba dawọ duro nibi kikọ, ni mo wa sọ iyẹn fun ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ, ni o wa sọ pe: «Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo».

[O ni alaafia] [Abu Daud ni o gba a wa]

الشرح

AbduLlaah ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si i– sọ pe: Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki n le baa de e mọlẹ pẹlu kikọ, ni awọn ọkunrin kan ninu Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko iyọnu ati ibinu, ti o si le ṣe aṣiṣe, ni mo ba dawọ duro nibi kikọ. Ni mo ba sọ fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nipa nkan ti wọn sọ, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ o wa sọ pe: Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ ni ọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo ni eyikeyi ìṣesí ti ko baa jẹ, ati ni asiko iyọnu ati ibinu. Ati pe Ọba ti ọla Rẹ ga ti sọ nipa Anabi Rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- pe: {Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú * Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i} [An-Najmu 3-4].

فوائد الحديث

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹni ti a sọ kuro nibi aṣisọ ni nibi nkan ti o ba jiṣẹ rẹ lati ọdọ Oluwa rẹ ti O tobi ti O gbọnngbọn, ni asiko ti o ba n yọnu ati igba ti o ba n binu.

Ojukokoro awọn saabe – ki Ọlọhun yọnu si wọn – lori ṣiṣọ sunnah ati mimu un de etiigbọ awọn eeyan.

Lilẹtọọ ibura fun anfaani kan koda lai beere fun ibura, gẹgẹ bii kikanpa mọ alamọri kan.

Kikọ imọ silẹ ninu awọn okunfa to pataki lati ṣọ imọ ni.

التصنيفات

Pàtàkì sunna ati ipò rẹ, Kikọ sunna Anọbi silẹ, Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-