Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i

Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i."

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye pé ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kò sì bá obinrin lopọ, itumọ ibalopọ ni ibasun ati awọn ohun ti o ṣiwaju rẹ̀ gẹgẹ bii ifẹnukonu ati ifarakanra, wọn si maa n túmọ̀ rẹ̀ si ọrọ buruku, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ àti ṣíṣe aburú. Ninu rírú ofin Ọlọhun ni ṣiṣe awọn èèwọ̀ gbígbé harami, yoo pada sile lati Hajji rẹ̀ ní ẹniti Ọlọhun ti darijin, gẹgẹ bi wọn ti n bi ọmọde lai ni ẹṣẹ kankan lọrun.

فوائد الحديث

Riru ofin Ọlọhun, bi o ti jẹ pe o jẹ eewọ ni gbogbo igba, o jẹ eewọ ti a kanpá mọ́ ni àsìkò Hajj, lati lè fi babara awọn iṣẹ Hajj.

A bí ènìyàn láìsí ẹ̀ṣẹ̀ kankan lọrun rẹ̀; Kò nii gbé ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn rù.

التصنيفات

‏Ọla ti n bẹ fun hajj ati Umrah