“Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa

“Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa.

[O daa] [Abu Daud ni o gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fún wa níbi kí a má maa ki ìrun ninu awọn ile wa, tí awọn ile naa yio waa da gẹgẹ bii itẹ́ awọn òkú, tí ẹnikẹni kò gbọdọ̀ kirun nibẹ. O sì kọ̀ fun wa lati maa ṣe àbẹ̀wò saare rẹ̀ léraléra ati imaa kójọ sibẹ ni igba gbogbo; nitori pe iyẹn jẹ́ ọna kan tí ó lè mu wa wọ inu ẹbọ. Ó paṣẹ pe ki a maa tọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun oun ni ibikibi lori ilẹ aye; nitori pe iyẹn yoo kàn án lara lati ọdọ ẹniti ó sunmọ ati ẹniti ó jinna bakan naa, nitori naa a o ni bukata si ki a maa paara ibi saare rẹ̀.

فوائد الحديث

kíkọ̀ fun wa kuro nibi kí a má maa jọsin fun Ọlọhun Ọba ninu awọn ile wa.

kíkọ̀ fun wa kuro nibi ìrìn-àjò lati lọ ṣabẹwo saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nítorí pé ó paṣẹ fun wa pe ki a maa ṣe asalatu fun oun, ó sì sọ pe yoo kan oun lara, ṣugbọn a lè ṣe irin-ajo lati lọ ṣabẹwo mọṣalaṣi Anabi kí a sì kirun ninu rẹ̀.

Èèwọ̀ ni ki a sọ abẹwo saare Anabi di ọdun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nipa pípàárà abẹwo saare rẹ̀ ni ọna kan ati asiko kan pato, bakan naa ni ṣiṣe abẹwo gbogbo saare.

Apọnle ti n bẹ fun Anabi lọdọ Oluwa rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pẹlu ṣíṣe ìtọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun Anabi lófin ní gbogbo ìgbà ati àyè.

Níwọ̀n ìgbà tí ìkọ̀fúnni kuro nibi kíkírun nibi awọn saare ti fẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn sahaaba; idi niyi ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fí ń kọ̀ fun wa pé a ò gbọdọ̀ ṣe awọn ile wa gẹgẹ bii itẹ́ saare tí wọn ò kí ń kírun nibẹ.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun awọn iṣẹ rere