Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná

Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná

Lati ọdọ Abdullah ọmọ ‘Amr - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlohun maa ba a - n pàṣẹ pé ki a gbé ìmọ̀ oun kaakiri, yala o jẹ lati inu Al-Qur’an ni tabi lati inu Sunna, koda ki nkan naa jẹ kekere gẹgẹ bii aayah kan pere lati inu Al-Qur’an tabi Hadiisi kan pere, pẹlu majẹmu pé ki olujiṣẹ naa jẹ́ onimimọ nipa nkan ti ó fẹ́ jiṣẹ rẹ̀, tí ó sì fẹ́ kéde rẹ̀. Lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣalaye pé ko si aburu pẹlu sisọrọ nipa awọn ọmọ Ísírẹ́lì, ati nipa awọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, pẹlu pé kó ṣá ti má tako ofin sharia tiwa. Lẹyin naa, ó wá wa ní isọra kuro nibi píparọ́ mọ́ òun, nitori pé ẹnikẹni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ mọ oun, kí ó yaa tètè gba aaye kalẹ̀ fun ara rẹ̀ ninu ina.

فوائد الحديث

Ìgbani níyànjú lati maa kéde òfin sharia Ọlọ́hun, àti pé ènìyàn gbọ́dọ̀ kéde ohun tí ó bá há sórí, tí ó sì gbágbọ̀yéé rẹ̀, koda bó jẹ́ pé díẹ̀ ni.

Ọ̀ranyàn ni wíwá ìmọ̀ ofin sharia; kí a lè jọsin fun Ọlọhun ní ìrọ̀rùn, kí a sì lè kede sharia Rẹ̀ ní àwòrán tó lalaafia.

Ọ̀ranyàn ni kí a ri i dájú pé èyíkéyìí hadiisi ní alaafia siwaju kí a tó kede rẹ̀, nitori kí a má baa kó sí inu ìlérí tó lekoko yii.

Ìgbani níyanju lati maa sọ ododo ati ìmáa ṣọra nibi ọrọ sisọ, kí a má baa kó sinu irọ́, paapaa julọ ninu ofin Ọlọhun Ọba.

التصنيفات

Pàtàkì sunna ati ipò rẹ, Idajọ pipepe soju ọna Ọlọhun