Kii ṣe ẹniti n fi dáadáa ṣẹ̀san dáadáa ni ó pé perepere nibi siso okùn-ẹbi, ṣugbọn oluso okùn-ẹbi gangan ni ẹniti ó jẹ́ pé nigba ti awọn eniyan bá já okùn-ẹbi rẹ̀ dànù, ó maa n so o padà

Kii ṣe ẹniti n fi dáadáa ṣẹ̀san dáadáa ni ó pé perepere nibi siso okùn-ẹbi, ṣugbọn oluso okùn-ẹbi gangan ni ẹniti ó jẹ́ pé nigba ti awọn eniyan bá já okùn-ẹbi rẹ̀ dànù, ó maa n so o padà

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o gba a wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - ó sọ pé: "Kii ṣe ẹniti n fi dáadáa ṣẹ̀san dáadáa ni ó pé perepere nibi siso okùn-ẹbi, ṣugbọn oluso okùn-ẹbi gangan ni ẹniti ó jẹ́ pé nigba ti awọn eniyan bá já okùn-ẹbi rẹ̀ dànù, ó maa n so o padà".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé dajudaju eniyan tó pé nibi siso okun-ẹbi ati ṣiṣe daadaa si awọn ibatan rẹ̀ kii ṣe eniyan tí ó ń san daadaa pẹlu daadaa nikan, bi ko ṣe pé ẹniti ó ń so okun-ẹbi gangan, tó sì pé nibi siso okun-ẹbi ni ẹnití o jẹ́ pé bí wọ́n bá já okun-ẹbi rẹ̀, ó maa so o padà, kódà bí wọ́n bá ṣe aburú si i; dáadáa ni oun maa ṣe sí wọn padà.

فوائد الحديث

Siso okun-ẹbi tí ó wà ní ibamu pẹlu Sharia ni pé kí o sopọ mọ awọn tí wọ́n bá já ọ danu kuro laarin wọn, ki o sì ṣamojukuro fun awọn ti wọ́n bá ṣabosi sí ọ, ki o sì fún awọn ti wọ́n bá ṣahun si ọ, kii ṣe pé ki o sopọ pẹlu sísẹ̀san iru nkan ti wọ́n ṣe si ọ.

Siso okun-ẹbi ni pé kí o mu de ọdọ wọn nkan tó bá rọ ọ lọrun ninu oore, bii owo, adura, pipaṣẹ nkan dáadáa, kikọ nkan aburu, ati iru bẹẹ, kí o sì ti aburu dànù fun wọn bí ó bá ti rọrun fun ọ.

التصنيفات

Awujọ ti Musulumi