Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe…

Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”

Lati ọdọ Ibn Abbas, ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”.

[Isnaadu rẹ daa] [Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ahmad]

الشرح

Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi, o si ba a sọro nipa ọrọ ara rẹ, lẹ́yìn naa o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ ati ohunkohun ti o ba fẹ”, Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, bá tako ọrọ yii o si sọ fun un pe sise idapọ fifẹ ẹda pẹ̀lú fifẹ Ọlohun pẹlu lẹ́tà “waw” jẹ ìsẹbọ kekere si Ọlọhun, ko si lẹtọọ fun Musulumi lati sọ ọ, Lẹ́yìn náà, ó ṣamọ̀nà rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà pé: “Ohunkóhun tí Ọlọ́hun nìkan ṣoṣo ba fẹ́,” nítorí náà ó maa ya Ọlọ́hun sọ́tọ̀ nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sì nii so fifẹ ẹni kankan mọ ọn pẹlu èyíkéyìí ninu iran asopọ.

فوائد الحديث

O jẹ ewọ lati sọ pe: “Ohun ti Ọlọhun fẹ ati ohun ti ìwọ naa ba fẹ,” ati ohun ti o jọ ọ ninu nnkan ti asopọ fifẹ ẹru mọ fifẹ ti Ọlọhun n bẹ nibẹ pẹlu lẹ́tà WAW; torí pé ẹbọ kekere ni.

Ijẹ ọranyan kikọ ohun burúkú.

Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – daabo bo ọgbà taohid, o si di àwọn ọ̀nà ẹbọ.

Nigba ti a ba n kọ aburu, o dara ki a dari ẹni ti a n pe si ibomiran ti o yẹ to si tọ́ lati fi kọ́ṣe Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -.

Idapọ laaarin ọrọ rẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a- ninu Hadiisi yii: “Ohunkohun ti Ọlọhun nikan ṣoṣo ba fẹ” ati ọrọ rẹ ninu Hadiisi miiran: “ Sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ohunkóhun tí ìwọ naa ba fẹ", ni pe o ni ẹ̀tọ́ ki èèyàn sọ pe: "Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ohunkóhun tí ìwọ naa ba fẹ", ṣùgbọ́n èyí tí ó ni ọlá jù ni gbólóhùn: "Ohunkohun ti Ọlọhun nikan ba fẹ".

O lẹtọọ lati sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ohunkóhun tí o ba fẹ,” ṣugbọn o dara julọ lati sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun nikan ba fẹ”.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah