“Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”

“Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”.

[O ni alaafia] [Ibnu Hibbaan ni o gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti iwa buruku nibi ole jija ni ẹni ti o maa n jale nibi irun rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe ẹni ti o ba mu owo ẹlomiran, o ṣeeṣe ki o ṣe anfaani pẹlu rẹ ni aye, yatọ si ole yii, dajudaju oun ja ẹtọ ara rẹ lole ninu ẹsan ati laada, wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni o maa ṣe jale ninu irun rẹ? O sọ pe: Ko nii ṣe rukuu rẹ laṣepe, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣepe; ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu pe ki o maa kanju nibi rukuu ati iforikanlẹ, ti ko nii mu mejeeji wa ni ona ti o pe.

فوائد الحديث

Pataki kiki irun daadaa ati mimu awọn origun rẹ wa pẹlu ifarabalẹ ati irẹlẹ.

Ṣíṣe iroyin ẹni ti ko ba ṣe rukuu rẹ ati iforikanlẹ rẹ laṣepe pẹlu pe ole ni lati leni sá kúrò nibẹ, ati lati tani ji si ṣíṣe e ni eewọ.

Jijẹ dandan ṣíṣe rukuu ati iforikanlẹ laṣepe nibi irun ati nínà tọ̀ọ̀ lẹ́yìn ti a ba gbori kúrò nibi mejeeji.

التصنيفات

Awọn origun irun, Iroyin irun, Awọn àṣìṣe awọn olukirun