Ti ẹ ba ti wa si aaye igbọnsẹ yin ẹ ko gbọdọ da oju kọ kibula, ẹ ko si tun gbọdọ da ẹyin kọ ọ, amọ ẹ daju kọ ila oorun tabi iwọ oorun

Ti ẹ ba ti wa si aaye igbọnsẹ yin ẹ ko gbọdọ da oju kọ kibula, ẹ ko si tun gbọdọ da ẹyin kọ ọ, amọ ẹ daju kọ ila oorun tabi iwọ oorun

Lati ọdọ Abu 'Ayyub Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i-, dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti ẹ ba ti wa si aaye igbọnsẹ yin ẹ ko gbọdọ da oju kọ kibula, ẹ ko si tun gbọdọ da ẹyin kọ ọ, amọ ẹ daju kọ ila oorun tabi iwọ oorun» Abu Ayyūb sọ pe: A wa si Shām ti a si ri awọn ile igbọnsẹ ti wọn ti mọ daju kọ kibula, nitori naa a maa n yẹ si ẹgbẹ, ti a si tun maa n wa aforijin Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun ẹni ti o ba fẹ gbọ bukaata itọ tabi igbẹ ki o da oju kọ kibula ati agbegbe kaaba, ki o si ma tun da ẹyin kọ ọ; amọ o jẹ dandan fun un ki o yi si ila oorun tabi iwọ oorun ti kibula rẹ ba jọ kibula awọn ara Madinah. Lẹyin naa ni Abu Ayyūb wa funni ni iro pe nígbà tí wọn de Shām wọn ri awọn ile igbọnsẹ nibẹ ti wọn ti pese kalẹ fun gbigbọ bukaata ti wọn da oju wọn kọ kaaba, nitori naa wọn maa n yi ara wọn kuro ni kibula, ti wọn si tun maa n toro aforijin Ọlọhun pẹlu bẹ́ẹ̀.

فوائد الحديث

Ọgbọn ti o n bẹ nibi ìyẹn ni gbigbe kaaba abiyi tobi ati ṣiṣe aponle rẹ.

Wíwá aforijin lẹyin jijade kuro ni aaye igbọ bukaata.

Didara ikọnilẹkọọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; latari pe nígbà tí o darukọ nkan ti wọn kọ, o tọka si eyi ti o lẹtọọ naa.

التصنيفات

Imu awọn ẹgbin kuro, Awọn ẹkọ bibiya bukaata