Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna

Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé dajudaju awọn nkan tí ẹ̀mí eniyan n fẹ́ ni o wa ní ayika Iná ọ̀run, gẹgẹ bii ṣiṣe awọn nkan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ tabi ikudiẹ-kaato nibi awọn ọranyan; Nitori naa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ifẹẹnu rẹ̀ nibi ìyẹn, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Ina ọ̀run, àti pé dajudaju àwọn nkan tí ẹmi eniyan koriira rẹ̀ ni o wa ní ayika Alujanna; gẹgẹ bii ṣíṣe àwọn nkan tí Ọlọhun pa wá láṣẹ rẹ̀ déédé ati gbigbe àwọn nkan eewọ jù sílẹ̀ àti ṣíṣe sùúrù lori wọn, tí eniyan bá wá tiraka, tí ó sì gbiyanju pẹ̀lú ẹmi ara rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Alujanna.

فوائد الحديث

Ninu awọn okunfa tí eniyan fi n kó sínú ifẹkufẹẹ adun aye ni kí èṣù kó ọ̀ṣọ́ bá awọn nkan naa, tí ó jẹ́ nkan buruku tí kò dara, títí eniyan o fi ri i pé ó dara, yoo sì ṣẹ́rí lọ si idi rẹ̀.

Àṣẹ jíjìnà sí awọn adùn aye tó jẹ́ eewọ; nitori pe ọ̀nà ati wọ iná ni, ati ṣiṣe suuru lori awọn nkan tí ẹmi wa koriira rẹ̀; nitori pe ọ̀nà ati wọ Alujanna ni.

Ọlá tí n bẹ fún jija ẹ̀mí ara ẹni lógun, ati gbígbìyànjú nibi ijọsin fun Ọlọhun, ati níní suuru lori awọn nnkan ti èèyàn koriira ati inira tí ó wà níbi titẹle ti Ọlọhun.

التصنيفات

Awọn iroyin alujanna