“Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”

“Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Jibril ko yẹ ni ẹni tí n pààrà fun un ti o si n pa a láṣẹ láti ni akolekan aládùúgbò ti ilé rẹ sunmọ, Mùsùlùmí ni tabi Kèfèrí, mọlẹbi ni tabi ẹni tí kii ṣe mọ̀lẹ́bí, pẹlu ṣiṣọ iwọ̀ rẹ, ki eeyan ma si fi suta kan an, ki èèyàn si maa ṣe daadaa si i, ki èèyàn si maa ṣe suuru lori suta rẹ, titi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi lérò pe imisi maa sọ̀kalẹ̀ pé ki a maa fun un ninu dúkìá aládùúgbò rẹ ti o ba fi silẹ lẹ́yìn iku rẹ latara bi o ṣe bàbàrà iwọ̀ rẹ, ati bi Jibril ṣe n pààrà rẹ.

فوائد الحديث

Titobi ẹtọ ti aládùúgbò ati ọranyan lati ṣe akiyesi iyẹn.

Títẹnu mọ́ ẹ̀tọ́ aládùúgbò pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ n béèrè fun pé kí a bọ̀wọ̀ fún un, ki a wa ki o nífẹ̀ẹ́ ẹni, ki a si ṣe daadaa si i, ki a si ma jẹ ki o ri ìpalára, ki a si maa bẹ ẹ wo ti o ba ṣe àìsàn, ki a si maa ki i nígbà ìdùnnú, ki a si ba a kẹ́dùn nígbà àjálù.

Bí ẹnu-ọ̀nà aládùúgbò bá ṣe sunmọ si, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀tọ́ rẹ̀ ṣe maa kanpá sí.

Pípé sharia nibi nǹkan ti o mu wa ninu nǹkan ti didara àwùjọ wa nínú ẹ, bii ṣíṣe dáadáa si awọn aládùúgbò, ati titi ìpalára kuro fun wọn.

التصنيفات

Ilaja ati awọn idajọ aládùúgbò