“Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”

“Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”

Lati ọdọ Abu Ayyub Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ki Mùsùlùmí yan ọmọ-ìyá rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí lodi kọjá ọjọ́ mẹ́ta, ti wọn maa pade ara wọn, ti wọn ko nii kí ara wọn, wọn ko si nii ba ara wọn sọ̀rọ̀. Ẹni tí ó ni ọlá ju ninu awọn mejeeji ti wọn n jà yii ni ẹni tí o ba n gbìyànjú lati mu odì kúrò, ti o maa wa kọ́kọ́ salamọ, ohun tí a gba lero pẹ̀lú HAJRU nibi ni odì nítorí ìpín ti ẹmi, ṣùgbọ́n odì nítorí tí Ọlọhun, gẹgẹ bii yiyan àwọn ẹlẹṣẹ lódì, ati awọn oni adadaalẹ, ati awọn ọrẹ burúkú, eléyìí ko ni asiko, bi ko ṣe pe o nii ṣe pẹ̀lú anfaani nibi odì, ti o si maa kúrò pẹ̀lú kikuro rẹ.

فوائد الحديث

Ṣíṣe odì ni ẹtọ fun ọjọ mẹta tabi ki o ma to bẹẹ, fun ti adamọ ti ọmọniyan, wọn wa yọnda odì fun ọjọ mẹta ki nǹkan ti o ṣẹri wa yẹn le lọ.

Ọla ti n bẹ fun salamọ, ati pe o maa mu ohun ti n bẹ ninu ẹmi kúrò, o si tun jẹ àmì fun ìfẹ́.

Ojúkòkòrò Isilaamu lori ijẹ ọmọ-iya ati ifẹ láàrin àwọn Musulumi.

التصنيفات

Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ, Odi yiyan ati awọn majẹmu rẹ, Awọn ẹkọ salamọ ati gbigba iyọnda