Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀

Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọhun Ọba ati awọn iṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọhun nikan ṣoṣo, tabi kí a sọ pé Anabi ní imọ kọ̀kọ̀, tabi ki a maa pe e papọ mọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe ṣe pẹlu Isa ọmọ Maria - ki alaafia Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa, Anabi ṣalaye pé ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun ni oun, ó sì paṣẹ pé ki a maa sọ nipa oun bayii pé: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀.

فوائد الحديث

Iṣọnilara kuro nibi titayọ aala ofin sharia nibi ẹyìn; nitori pe ó máa n ja si ẹbọ ni.

Ohun ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kilọ fun wa nipa rẹ̀, ó ti ṣẹlẹ ninu ijọ yii, nitori awọn ẹgbẹ kan ti tayọ aala lara Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ẹgbẹ kan sì tayọ aala lara awọn ara ile Anabi, awọn ẹgbẹ kan tún tayọ aala lara awọn wòlíì Ọlọhun, gbogbo wọn bá kó sinu ẹbọ.

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ẹru Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ẹru ti Allah ń rè ni oun, nitori naa kò lẹtọọ ki a dari nkankan ninu awọn ìròyìn ẹ̀ṣà Oluwa si ọdọ rẹ̀.

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ojiṣẹ Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ojiṣẹ kan lati ọdọ Ọlọhun ni oun, nitori naa ọranyan ni ki a pe e lódodo ki a si tẹle e.

التصنيفات

Taohiid ti uluuhiyyah